Ezekiel 27:30-34

30Wọn yóò jẹ́ kí a gbọ́ ohùn wọn lòdì sí ọ
wọn yóò sì sọkún kíkorò lé ọ lórí
wọn yóò ku eruku lé orí ara wọn
wọn yóò sì yí ara wọn nínú eérú.
31Wọn yóò fá irun orí wọn nítorí rẹ
wọn yóò wọ aṣọ yíya
wọn yóò pohùnréré ẹkún pẹ̀lú
ìkorò ọkàn nítorí rẹ
pẹ̀lú ohùn réré ẹkún kíkorò.
32Àti nínú arò wọn ni wọn yóò sì pohùnréré ẹkún fún ọ
wọn yóò sì pohùnréré ẹkún sórí rẹ, wí pé:
“Ta ni ó dàbí Tire
èyí tí ó parun ní àárín Òkun?”
33Nígbà tí ọjà títà rẹ ti Òkun jáde wá
ìwọ tẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè lọ́rùn
ìwọ fi ọrọ̀ tí ó pọ̀ àti àwọn ọjà títà rẹ
sọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀.
34Ní ìsinsin yìí tí Òkun fọ ọ túútúú
nínú ibú omi;
nítorí náà òwò rẹ àti gbogbo ẹgbẹ́ rẹ
ní àárín rẹ,
ni yóò ṣubú.
Copyright information for YorBMYO